Ṣiṣe ipinnu lati f’orukọsilẹ ninu Iwadii Iṣegun Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde
Ohun ti o Pe Fun Lati Dara Pọ mọ RISE UP
Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde
Awọn Eredi ti RISE UP Fi Le Jẹ Ohun to Yẹ
Àwọn Osuwọn Àmúyẹ:
- O jẹ ọmọ ọdun 16 tabi ju bẹẹ lọ
- O ni àìsàn fòní kú fọ̀la nde
- Bi iwọ tabi ẹnikeji rẹ ba ni ipa lati loyun, ẹ gbọdọ gba lati lo awọn fọọmu ifeto si ọmọ bibi 2
- O ti ni o keere ju awọn isoro irora 2 sugbọn ti ko ju 10 lọ ni ọdun to kọja
- Ti a tumọ si irora to nilo akiyesi iṣegun ati itọju eyiti o sẹlẹ nipa irora aya lile, idide nkan ọmọkunrin fun igba pipẹ, tabi idiwọ sẹẹli ẹjẹ pupa ninu ẹdọki, àmọ́, tabi ni ibomiran ninu ara
- O ni ipele hẹmoglobiiinì laarin 5.5 ati 10.5 g/dL
- Bi o ba lo hydroxyurea, ìlò hydroxyurea rẹ gbọdọ wà bakan naa fun o keere ju ọjọ 90 ki o to bẹrẹ oogun iwadii yii
Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde
Awọn Eredi ti RISE UP Fi Le Má Jẹ Ohun to Yẹ
- Bi o ba loyun tabi nfun ọmọ l’ọyan
- Bi o ba ngba ẹjẹ ti a fi si eto loorekoore
- Bi o ba ni eyikeyi àìsàn ẹ̀dọ̀ki àti òrónro, eyiti o kan ẹdọki tabi apo òrónro
- Bi o ba ni arun kidirin lile
- Bi o ba ti gba itọju jiini tabi ṣe ipaarọ mudunmudun inu egun tabi opo sẹẹli ri
- Bi o ba ngba itọju fun àìsàn fòní kú fọ̀la nde lọwọlọwọ (bii voxelotor, crizanlizumab, tabi L-glutamine), laisi hydroxyurea nibẹ
- Bi o ba ngba awọn itọju to nru isẹda ẹ̀jẹ̀ soke bii ẹritropoiẹtiinì
Nini ikopa giga ninu awọn idanwo iṣegun maa nje ki awọn isayan ati anfaani to wa larọwọto wa han dedere. O s’anfaani fun didara gbogbo eniyan.
Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde