AWỌN IBEERE TI O MAA NSABA WAYE ati awọn Ohun Elo

Awọn idahun Fun awọn Akọni

 / 
Kinni yoo kọkọ ṣẹlẹ̀ bi mo ba pinnu lati dara pọ?

Ki a to f’orukọ rẹ silẹ lẹkunrẹrẹ gẹgẹ bi olukopa kan ninu RISE UP, ikọ ilera kan yoo ṣe ayẹwo itan itọju ati ilera rẹ lati rii daju wipe o le kopa. Wo Ṣiṣe Ipinnu lati F’orukọsilẹ lati gba oye ti o dara sii bi idanwo naa ba tọ fun ọ.

Kinni awọn abajade lati abala 2?

Abala 2 ti iwadii RISE UP agbaye ṣe afihan igbesoke pataki ninu bi hẹmoglobiinì ṣe nfesi ni ọsẹ 12 pẹlu mitapivat ni afiwe si arọ́pò.

Apapọ awọn agbawosan 79 lo f’orukọsilẹ ni abala 2 iwadii RISE UP agbaye. Bi awọn alaisan 27 ti gba placebo, awọn alaisan 52 lo gba mitapivat.

Mitapivat mu ki awọn asami iparun sẹẹli ẹjẹ pupa ati iṣẹda sẹẹli ẹjẹ pupa gberu ni afiwe si arọ́pò. Awọn asami fun iparun sẹẹli ẹjẹ pupa nsọ fun ọ bi awọn sẹẹli ẹjẹ pupa rẹ ṣe ni ilera si, ati wipe asami fun iṣẹda sẹẹli ẹjẹ pupa nsọ fun ọ bi a ti nyara pese awọn sẹẹli ẹjẹ pupa ati awọn sẹẹli ẹjẹ yooku.

Mitapivat tun s’afihan ju idinku 50% ninu isoro irora àìsàn fòní kú fọ̀la nde (SCPC) ni afiwe si arọ́pò.

Njẹ o nlo awọn olupese kan naa ti o lo fun abala 2 ati abala 3?

Bẹẹni, awọn olupese kan naa ti a lo ni abala 2 ni a o lo fun abala 3, ati awọn afikun olupese kan bakan naa.

Bawo ni a ṣe mọ nipa mitapivat si?

A ti ṣe iwadii Mitapivat lati Osu Kẹta Ọdún 2014.

Awọn alaisan to ju 700 lọ, pẹlu awọn oluyọnda ti ara wọn ya, ni a ti tọju pẹlu mitapivat fun orisirisi arun.

A ti ṣe iwadii Mitapivat fun o lé ní ọdun marun.

Kinni “itọju itunṣe arun” tumọ si fun mi gan? Ṣe eyi le yí DNA mi padà?

Mitapivat gẹgẹ bi itọju itunṣe arun le jẹ ki arun rẹ dara sii, sugbọn ko nii yí DNA rẹ padà.

Njẹ mo ni idaniloju wipe mo wa lori itọju?

Ní abala 3 iṣẹ́ ìwádìí yìí, fun gbogbo agbawosan mẹta to nkopa, meji yoo wa lori mitapivat ti ẹyọ kan yoo si wa lori arọ́pò.

Ẹwẹ, akoko iwadii afikun akọle-sisi sílẹ̀ kan ti kii ṣe dandan ọlọdun 4 wa nibi ti gbogbo eniyan ti ngba mitapivat.

Njẹ mitapivat l’aabo?

Eredi abala 3 yii ni lati mọ boya mitapivat ni aabo o si wulo.

Ko si awọn agbawosan to wa lori idaduro itọju mitapivat tabi arọ́pò latari awọn àtúnbọ̀tán ni abala iwadii 2.

Jakejado gbogbo iwadii mitapivat, lára awọn àtúnbọ̀tán ti a ri ninu awọn agbawosan 10% tabi ju bẹẹ lọ ni ori fifọ, rirẹ, èébì tí ó nléni, irora orikeerikee ara, ati COVID-19.

Njẹ mo le lo awọn oogun miran lasiko idanwo naa?

Mitapivat le ni ipa lori ọna ti awọn oogun miran ngba siṣẹ, ati wipe awọn oogun miran le ni ipa lori bi mitapivat ṣe nsiṣẹ. Lilo mitalivat pẹlu awọn oogun miiran le fa awọn àtúnbọ̀tán pẹlu.

Ba dokita rẹ sọrọ nipa awọn oogun ti o nlo lọwọlọwọ (titi kan awọn oogun ti wọn kọ fun ọ, awọn oogun ati ohun amarajipepe orí igbá, ati ohunkohun toni eso ajara ninu). Dokita iwadii rẹ yoo jẹ ki o mọ awọn oogun ti ko lewu lati maa lo nigbati o ba wa lori mitapivat.

Bawo ni mo ṣe nilo lati kopa ninu iwadii naa pẹ́ tó?

Bi o ba f’orukọsilẹ, ikopa ninu abala iwadii 3 jẹ ọdun kan.

Njẹ ẹ ngba awọn agbawosan tuntun fun abala 3?

Bẹẹni, a o si fẹ ki o darapọ mọ iṣẹ naa. F’orukọsilẹ nibi.

Awọn ile-iwosan wo lo nkopa ninu abala 3?

Nàìjíríà

  • The University of Nigeria Teaching HospiatalOlubasọrọ: 2348888888888
  • Lagos University Teaching Hospital HaematologyOlubasọrọ: 2348023535659
  • University of Abuja Teaching HospitalOlubasọrọ: 2348130610603
  • Barau Dikko Teaching Hospital (BDTH), KadunaOlubasọrọ: 2348037051283
  • National Hospital AbujaOlubasọrọ: 2348180341795
  • University of Calabar Teaching HospitalOlubasọrọ: 2348036742377

Kinni itumọ “ohun ti arọ́pò ndari, ifọju-meji”?

Arọ́pò jẹ oogun to dabi oogun iwadii sugbọn ko ni oogun Kankan ninu. Awọn arọ́pò maa npese ọna kan lati s’afiwe awọn abajade ti a pese nipasẹ oogun iwadii. "Ifọju-meji" tumọ si wipe iwọ tabi dokita rẹ ko nii mọ boya o nlo arọ́pò tabi oogun iwadii, ki o ma baa ni ipa lori awọn abajade tabi agbeyẹwo naa.

Bawo ni a ó ti dáàbò bo asiri mi?

Jakejado iwadii naa, orukọ rẹ ati gbogbo iwifunni iṣegun ara ẹni rẹ yoo wa ni aṣiri patapata. Olukopa kọọkan ninu iwadii naa ni a o fun ni ohun idanimọ ara ọtọ kan. Awọn akọsilẹ ati détà ti a gba jakejado iwadii naa ko nii ni orukọ rẹ tabi iwifunni idanimọ ara ẹni rẹ, sugbọn yoo ni ohun idanimọ ara ọtọ.

Iru iranlọwọ wo ni mo le reti lasiko iwadii naa?

O ni awọn ohun miran to nsẹlẹ ninu igbe-aye rẹ, ati wipe gbigbogunti àìsàn fòní kú fọ̀la nde lojoojumọ jẹ ipenija nla. Bi o ba nilo iranlọwọ lasiko iwadii naa, atilẹyin le wa larọwọto fun:

  • Awọn olutọju
  • Itọju ọmọ
  • Irinajo
  • Igbokegbodo ọkọ
  • Owo iranwọ
  • Awọn nọọsi fun awọn abẹwo ọna jijin
  • Awọn abẹwo ori ayelujara

Awọn isẹ itọju oke yii da lori awọn ilana agbegbe ati orilẹ̀-èdè. Jọwọ ṣe ayẹwo pẹlu oluwadii agbegbe lati fi idi awọn iṣẹ itọju to wa larọwọto ni agbegbe rẹ mulẹ. Iwifunni siwaju sii nipa atilẹyin yoo wa larọwọto ni oju-ewe ayelujara iforukọsilẹ rẹ ni pato.

Ọkan ninu awọn iwuri mi to tobi julọ (lati gbogunti) ni awọn eniyan ninu awujọ àìsàn fòní kú fọ̀la nde.

Teonna,

Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde

@sicklequeent