Awọn Ìlànà Ilo
AWỌN ILANA ATI ISE TI NDARI ILO OJU-EWE AYELUJARA AGIOS
ORO AKOSO
Kaabọ si oju-ewe ayelujara idanwo isegun RISE UP Agios (”oju-ewe ayelujara”). Agios sẹda ati s’amojuto oju-ewe ayelujara yii lati pese iwifun si ati sọrọ daradara pẹlu olutọju, alaisan, afowopaowo ati awọn yooku ti o le niifẹ si kikọ sii nipa Agios ati awọn ọja ati isẹ ti o npese. O le lo oju-ewe ayelujara yii, bi o ba sowọpọ pẹlu awọn ilana ati ise wọnyii. Ni afikun si awọn ilana ati ise wọnyi, o gbọdọ kaa pẹlu ki o si mọ awọn ipese Ilana Asiri wa, eyiti o sọ nipa awọn ise Agios nipa akopọ ati ilo iwifun ara-ẹni, ati awọn ilana yooku ti o ndari awọn apa oju-ewe ayelujara yooku.
IFỌWỌSI RẸ SI AWỌN ILANA ATI ISE WỌNYI
Jọwọ lo awọn isẹju diẹ lati s’atunyẹwo awọn ilana ati ise wọnyi daradara. Nipa wiwọle si ati lilo oju-ewe ayelujara yii o ti gba lati tẹle ti awọn ilana ati ise wọnyi. Bi o ko ba faramọ lati tẹle ki awọn ilana ati ise wọnyi, o le ma raaye wọle, lo tabi gba awọn eronja silẹ lati oju-ewe ayelujara yii.
AWỌN ILANA ATI ISẸ WỌNYI LE YIPADA
Agios ni ẹtọ lati se imudojuiwọn tabi ṣe atunṣe awọn ilana ati isẹ wọnyi ni igbakugba laisi ifilọ isaaju. Ilo oju-ewe ayelujara yii ni titẹle eyikeyi iyipada se afihan ifaramọ rẹ lati tẹle ki awọn ilana ati ise naa gege bi a se yipada. Fun idi eyi, a gba ọ niyanju lati se atunyẹwo awọn ilana ati ise wọnyi ni gbogbo igba ti o ba lo oju-ewe ayelujara yii.
Awọn ilana ati ise wọnyi ni a se atunyẹwo rẹ ni Osu Keje, ọjọ 28, Ọdun 2018.