Awọn Itan Akọni

Gbogbo AKỌNI Ni Ó Ní Itan kan

Teonna, Sickle Cell Warrior
TEONNA

Mo ṣì ni ireti fun ọjọ iwaju nipa siṣe ojuse ninu awujọ Akọni.

https://www.instagram.com/sicklequeent/ @sicklequeent

Q: Kinni o tumọsi si fún ọ lati jẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde?

A: Fun emi, jijẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde tumọsi nini aaye lati ṣegun ọpọlọpọ ipenja ti a máa ndojukọ pẹlu arun yii.

Q: Kinni eredi ti o fi RISE UP?

A: Gbogbo igba ni mo nwa awọn ọna lati mu ki awọn nkan dara síi fun awọn Akọni to wá lẹyin mi. Awọn itọju ati idanwo iṣegun tuntun tí ó lè mu ki nkan dara síi maa njẹ́ kí ara mi yá gágá jùlọ.

Tristian, Sickle Cell Warrior
TRISTIAN

Gẹgẹbi Akọni, a máa nja fun ara wa ati fun ẹnikọọkan.

Q: Kinni o tumọsi si fún ọ lati jẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde?

A: Ori mi wu wipe mo le lo ohun mi fun iran to nbọ pẹlu àìsàn fòní kú fọ̀la nde. Mo ti jẹ ki ọpọ eniyan mọ asiṣe wọn nigba ti o ba debi ohun ti mo le ṣe.

Q: Kinni eredi ti o fi RISE UP?

A: Awọn Akọni lagbara síi tí wọ́n bá wà papọ. Bi a ba foju si itẹsiwaju ti a nní, a ko nii jẹ ki àìsàn fòní kú fọ̀la nde ṣe àpèjúwe wa.

Dominique, Sickle Cell Warrior
DOMINIQUE

Gẹgẹbi Akọni, mo ṣì nireti mo si kọ lati gbe ninu ẹru.

https://www.twitter.com/sickle1000/ @sickle1000

Q: Kinni o tumọsi si fún ọ lati jẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde?

A: Lati jẹ Akọni wa nipa ipamọra. Mo gbiyanju lati gbadun gbogbo ọjọ, pẹlu bi àìsàn fòní kú fọ̀la nde mi ti nmu ki nronú. Iyẹn si mu mi l’agbara sii.

Q: Kinni eredi ti o fi RISE UP?

A: O ṣe pataki lati dara pọ mọ awọn idanwo iṣegun bii RISE UP nitori pé ó wa nipa fifi awọn eniyan toni àìsàn fòní kú fọ̀la nde ṣe akọkọ ati liloye iwoye wa. Bi awọn tí ó pọ̀ síi nínú àwọn Akọni awujọ ṣe nkopa, awọn anfaani siwaju sii le wa larọwọto.

Golie, Sickle Cell Warrior
GOLIE

Lati jẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde tumọsi pe o jẹ jagunjagun.

https://www.instagram.com/golielorenzo/ @golielorenzo

Q: Kinni o tumọsi si fún ọ lati jẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde?

A: Mo wo awọn Akọni akẹgbẹ́ mi mo si gba ìṣíníyè. Gbogbo wa fojusi wiwa awọn anfaani lati mu wa tẹsiwaju. Bi aaye kankan ba wa fun igbe-aye toni àìsàn fòní kú fọ̀la nde lati yatọ lọla ju ohun ti mo ni iriri rẹ loni lọ, nigba naa iyẹn yoo fun mi ni ireti nigba gbogbo.

Q: Kinni eredi ti o fi RISE UP?

A: O ṣe pataki ki a kopa ninu awọn idanwo iṣegun bii RISE UP, kii ṣe fun ẹnikọọkan wa, sugbọn fun awujọ Akọni tí ó tóbi síi. A nilo lati rii daju wipe iran awọn Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde to nbọ ni awọn anfaani ilera to dara síi.

Mia, Sickle Cell Warrior
MIA

Awọn Akọni nwo Akọniàìsàn fòní kú fọ̀la nde pẹlu ironilagbara.

Q: Kinni o tumọsi si fún ọ lati jẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde?

A: Jijẹ Akọni kan wa nipa siṣe iṣẹ lati bori awọn ipenija. O ngbiyanju lati maṣe jẹ ki àìsàn fòní kú fọ̀la nde da ọ duro, koda ni awọn ọjọ to le síi.

Q: Kinni eredi ti o fi RISE UP?

A: Mo fẹ ran awọn Akọni lọwọ lati ri àwọn anfaani fun itura. Awọn idanwo iṣegun bii RISE UP le yí bi a ti nni iriri àìsàn fòní kú fọ̀la nde padà. O wa nipa gbigba wa laaye lati siṣẹ kí a sì pese fun idile wa, lo akoko pataki pẹlu awọn olufẹ wa, ki a si gbadun igbe-aye wa lapapọ.

Blaze, Sickle Cell Warrior
BLAZE

Pariwo. Jẹki o le. Gbohun soke. Ṣe alagbawi. Wọn ko nii fi wa sẹyin.

https://www.instagram.com/highplaceblaze/ @highplaceblaze
DeMetrious, Sickle Cell Warrior
DeMITRIOUS

Dara pọ mọ RISE UP gẹgẹ bi Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde kan ti s’afihan àwọn agbara mi ti nko mọ pe mo ni rárá.

Q: Kinni o tumọsi si fún ọ lati jẹ Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde?

A: Gẹgẹ bi awọn Akọni Àìsàn Fòní Kú Fọ̀la Nde, a ṣe pataki nitooto. A lagbara nitori a nilo lati níi. O nfun mi ni ireti fun ọjọ iwaju ni imọ wipe mo nṣa ipa mi lati ran ara mi lọwọ, ati awọn ẹlòmiran, ti ngbe pẹlu àìsàn fòní kú fọ̀la nde.

Q: Kinni eredi ti o fi RISE UP?

A: O ṣe pataki lati ni igboya, lati sọrọ soke fun àìsàn fòní kú fọ̀la nde, ki a si gbáradì.